Orin Dafidi 126 - Yoruba YBCV

← Books

Orin Dafidi

Yoruba YBCV
| 6 of 6 verses

1 NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá.

2 Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn.

3 Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀.

4 Oluwa mu ikólọ wa pada, bi iṣan-omi ni gusu.

5 Awọn ti nfi omije fún irugbin yio fi ayọ ka.

6 Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ̀ pada wá, yio si rù iti rẹ̀.