Orin Dafidi 140 - Yoruba YBCV

← Books

Orin Dafidi

Yoruba YBCV
| 13 of 13 verses

1 OLUWA gbà mi lọwọ ọkunrin buburu nì, yọ mi lọwọ ọkunrin ìka nì;

2 Ẹniti nrò ìwa-buburu ni inu wọn; nigbagbogbo ni nwọn nrú ìja soke si mi.

3 Nwọn ti pọ́n ahọn wọn bi ejo; oro pãmọlẹ mbẹ li abẹ ète wọn.

4 Oluwa, pa mi mọ́ kuro lọwọ enia buburu; yọ mi kuro lọwọ ọkunrin ìka nì; ẹniti o ti pinnu rẹ̀ lati bì ìrin mi ṣubu.

5 Awọn agberaga dẹ pakute silẹ fun mi, ati okùn; nwọn ti nà àwọn lẹba ọ̀na; nwọn ti kẹkùn silẹ fun mi.

6 Emi wi fun Oluwa pe, iwọ li Ọlọrun mi: Oluwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi.

7 Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi, iwọ li o bò ori mi mọlẹ li ọjọ ìja.

8 Oluwa, máṣe fi ifẹ enia buburu fun u: máṣe kún ọgbọ́n buburu rẹ̀ lọwọ: ki nwọn ki o má ba gbé ara wọn ga.

9 Bi o ṣe ti ori awọn ti o yi mi ká kiri ni, jẹ ki ìka ète ara wọn ki o bò wọn mọlẹ.

10 A o da ẹyin iná si wọn lara: on o wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin, ki nwọn ki o má le dide mọ́.

11 Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu.

12 Emi mọ̀ pe, Oluwa yio mu ọ̀ran olupọnju duro, ati are awọn talaka.

13 Nitõtọ awọn olododo yio ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ: awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ma gbe iwaju rẹ.